Saturday, May 1, 2010

ORIKI OLORUN (in Yoruba)

Oba tin be ki bebe o to maa be
Baba alai ni baba, oko okpo
Oba tinshi ilekun teni kan oleti,

Oba tin ti ilekun teni kan ole shi
Ogbo ti kii-ti
Omini mini tin mi ile aye
Okunrin ogun…Erin lakatabu
Ogbamu gbamu oju orun oshe gbamu
Kiniun eyaa Judah, ekun oko Faraoh

Gbongbo idile Jesse
Eleyinju ina,
Inajojo, Eru Jojo
Ashoro kolu bii ogiri gbigbe
Oba tin san lawo sanma ti awon alaimokan npe ni sango
Abiyamo lojo ija, abiyamo lojo ishoro
Kabiesi ti awon agba agba merin le logun foribale fun, ti won ke mimo, mimo, mimo
Eleyinjuana oba tio ngba okan irora lowo ibanuje
Alamo tin mo ori eda
Atori ina tina satani sare
Baba mimo, Omo mimo, Emi mimo
Oba to ngbe nu wundia shola, oro gbe inu omo eniyan foun
Ariiro ala! Oba to gbe iku mi nii isegun,

Obiriikiti oba to kpa oko iku da laye
Eleti gbaroye eda
Arewa ti n be lorun, oba waa, oba woo, oba wawa wowo
Pari pari ola

Alfa ati Omiga
Ibere ati Opin
Ale we le se
Ale se le wi
Arugbo ojo
A yin yin tan Eledumare.
Oba adeda Aseda
Ameda, Aweda
Oba tinje emi ni emi ni
Oba tinje emi ni mase beru
Oba mimo, tin wo mimo
Ti'nso mimo, tinje mimo
O ranmo nise faya ti
Awiiro alaafia
Adagba matepa ojo
Adagba ma paro oye
Oba nla tinf'oba je
Oba ti kii ku
Oba to to to bi aro
Eledumare, Eledumare
Kabio masi, Kabi yi osi

Oda da, to da gbogbo aye, ologo didan
O gbi gba ti ngba alai lara
Oka soso adaba ti nmi igbo kiji kiji
Omi mo to mo iye awa eda to da
Egbo lehin eni ada loro

A ko ma ti ika lehin
Oba nla ti nfi ola wo ni bi aso
Otiti nla ato fi ara ti bi oke
Ounje nla ato fi bori ibi
Baba mi, oro nla ojo nla tobori Ogbele
Oba nti je emi ni lojo gbogbo
Eru Jeje ti nbe leti okun pupa
Oju kan nti wo igba aye
Olorun ajulo, atobiju iba re
Aye ka o won ko ri e ka
Aye wa o titi wo ko ri o
Won ba e nibi toju gbogbo aye lo
Eni ti o se ohun ti o tobi, ti a ko le se awari
Ohun iyanu laini iye
Oba aiku airi
Orisun ogbon Olubukun julo
Ologo julo iba re
Olorun ti ki rin irin ajo
Okan naa loni, okan naa lana, oba titi ayeraye
Oyigiyigi
-Atobiju oba iyanu
-Ologo mimo julo.
-Oba aseyi owu
-Oba awimayehun,asoro ma tase
--Oba to lohun gbogbo,to si le sohun gbogbo
Okan loba,
ijoye le kpe ogbon
olorun oba alagbara
olorun oba, okiki imole
gbirin leyin asododo
irawo owuro, oko maria
Oba mi okiki okaka, okaka okiki
ti n ki omo re leyin, kiki okiki
kiki imole, kiki ogo
oba mi oba adun bii oyin
Alagbara ninu awon orun
Oba ti o ti wa ki aiye to wa
Oba ti o wa, nigba ti aiye ko si mo

Kabiyesi Oba Alagbara giga
Oba awon oba,
Olorun awon Olorun

Akoda aye
Aseda Orun
Awamaridi
Apata Ayeraye,
Arugbo Ojo
Atobiju,
Atofarati bi oke,
Ato ba jaiye,
Alade Alafia,
Alade Wura,
Awole iro tipiletipile,
Alagbada Ina,
Alawo tele oorun,
Awogba arun magbeje,
Abeti lu kara bi ajere,
Atayero bi agogo,
Alagbede ode orun,
Arinu rode,
Olumoran okan,

Adake dajo
Akiri sore,
Afunnima se regun,
Apanla to sole ayero,
Alewi lese, Alese lewi,
Akiikitan, Ayiiyintan, Apeepetan,
Awimayehun,
Adimula,
Adimule,
Adesina ti sina aye f’eda
A joba mati,

Adagba ma tepa ojo
Adagba ma paro oye
A ja segun

Abiyamo lojo ija
Alatunse
Alaabo
A ji dara
A gbomo lowo iku
A ji pa ojo iku da
Aji bori oso
Ayipinu Esu pada
Ate rere kari aye
Agbeni ma deyin
Olusegun,
Alabaro
Aduro gbonin gboin leyin asotito
Olu Orun tinje Emi ni
Oluwa awon Oluwa
Olorun Imole
Oloore Ofe
Oga Ogo
Obangiji
Oluso agutan eni tire
Olowo gbogboro tiiyo omo re lofin
Olutunu (Comforter)
Olugbeja (Defender)
Oludande (Deliverer)
Olupamo (Protector)
Olukoni (Teacher)
Olupese (Provider)
Olubunkun (Benefactor)
Eru jeje leti okun pupa
Ako ma tika lehin
Ijinle ife
Ipin lese ohun gbogbo
Oba iyanu (AWESOME GOD)
Irawo Owuro
Jehovah Jireh
Jehovah Nissi
Jehovah Shalom
Jehovah Shama
Jehovah Rapha
Jehovah El Shaddai
Olorun Meshaki, Olorun Sederaki ati Abednego
Olorun Arahamu, Isaac ati Jacobu
Oba to la oju afoju

Oba to nji oku dide
Oba to po nipa ati agbara
Olorun owu (JEALOUS GOD)
Oba to pa kiniun lenu mo fun Daniel
Oba to ta oju orun bora bi aso
Oba to fi gbogbo agbaye se apoti itise re
Oba tin la ono nibi ti ona kosi
Oba to mu riri jade ninu airi
Oba Ibere ati opin ohun gbogbo
Oba ti ngbe niiga loju aninilara
Oba Aiku
Oba Airi
Oba a soro ma ye

Oba ti ko ni ibere ti ko si lopin
Kaabiyesi ooooooo

Mimo! Mimo!! Mimo!!!

Oba awon oba

35 comments:

  1. Can You please attach an audio clip of this Oriki so one can appreciate the accent and pronunciation
    Of the words, thanks.

    ReplyDelete
  2. Good job, the mighty God will put more effort to move forward.

    ReplyDelete
  3. Great.. Can we get the English version of this oriki? God bless u

    ReplyDelete
  4. He who work for God shall never lack. God almighty will grant you more understanding in Jesus name.

    ReplyDelete
  5. it is well with you............

    ReplyDelete
  6. An audio with this will be more blessings. Pls can the audio be attached? Thank you.

    ReplyDelete
  7. Great work done bro! Your light will never diminish IJN, you will grow in HIS wisdom. Keep up the good work

    ReplyDelete
  8. God continue to bless you, Amen.

    ReplyDelete
  9. This is overwhelming, so inspiring,
    half of the glory of our God is yet to be told.

    ReplyDelete
  10. IH MY GOD, SPIRIT OF GOD IS FEELING ME NOW. THNKS

    ReplyDelete
  11. Please may your blessings and prayers come forth with me and my loved ones thru blood and with spirit... I call upon the most highest in Jesus name I cry that soon we may rejoice and sit amongst those who have been in a state of corrupted knowledge and those that lack strength and wisdom and not only from drugs and alcohol but from pain and deliver us from evil that we will give them our hand to stand together without reason unite and become more powerful as a result of our circle.

    ReplyDelete
  12. God bless you sir, this is inspiring

    ReplyDelete
  13. God bless you sir, this is inspiring

    ReplyDelete
  14. God bless your ministry. Very impressive. About the audio..

    ReplyDelete
  15. Is asudedebiojo part of oriki olodumare

    ReplyDelete
  16. Fantastic job, I was looking for just one name, now I know so many. God bless you

    ReplyDelete